visualizaciones de letras 4
Letra

    T'a l'ó wà ní'bẹ? T'a l'ó wà, t'á ó pè ní'ṣẹ'?
    Àwọn ọrẹ wa wọn wà ní'bẹ', wọn pọ t'a pè ní'ṣẹ o

    Wọn mí w'ọ'nà f'ẹ'ni ńṣì'nà
    Wọn mí là'nà f'ẹ'ni nrìn bọ'
    Wọn mí gb'èrò wípé k'ó lè da
    Wọn mí ṣ'ìpẹ' f'ẹ'ni nṣ'ọ'fọ'
    Wọn mí pèsè f'aláìrí
    Wọn mí ṣè'tò wípé, wípé k'ó lè da

    Ẹgbẹ aláyọ', ẹgbẹ'oníre ńpè yín sẹ
    Àwọn ọrẹ wa wọn wà ní'bẹ', wọn pọ' t'a pè ní'ṣẹ o

    Wọn mí gbè'jà f'ẹ'ni ńjà'jà rere
    Wọn mí p'ẹ'tù sí'nú fùfù
    Wọn mí gb'èrò wípé k'ó lè da o
    Wọn mí wò'kè f'ẹ'ni ńwo'lẹ
    Wọn mí wo'lẹ' f'ẹ'ni ńwòké
    Wọn mí ṣè'tò wípé, wípé k'ó lè da

    Gbogbo ẹdá mà la pè, gbogbo yín mà la pè ní'ṣẹ'
    Àwọn ọrẹ wa wọn wà ní'bẹ', wọn pọ t'a pè ní'ṣẹ o

    Wọn mí w'ọ'nà f'ẹ'ni ńṣì'nà
    Wọn mí là'nà f'ẹ'ni ńrìn bọ
    Wọn mí gb'èrò wípé k'ó lè da o
    Wọn mí ṣ'ìpẹ' f'ẹ'ni ńṣ'ọfọ
    Wọn mí pèsè f'aláìrí
    Wọn mí ṣè'tò wípé, wípé k'ó lè da o

    Wọn mí gbè'jà f'ẹ'ni ńjà'jà rere
    Wọn mí p'ẹ'tù sí'nú fùfù
    Wọn mí gb'èrò wípé k'ó lè da o
    Wọn mí wò'kè f'ẹ'ni ńwo'lẹ
    Wọn mí wo'lẹ' f'ẹ'ni ńwò'kè
    Wọn mí ṣè'tò wípé, wípé k'ó lè da

    À fò, à lé ténté, à fò àwa d'ọ'rẹ' ìdùnnú
    (À fò, à lé ténté, à fò) àwa jogún ìdẹ'ra
    (À fò, à lé ténté, à fò) àwa bo'rí àìmọkan
    (À fò, à lé ténté, à fò) àwa bo'rí ìkórira
    (À fò, à lé ténté, à fò) àwa bo'rí ìwà ibi
    (À fò, à lé ténté, à fò) àwa d'ọrẹ ìdùnnú
    (À fò, à lé ténté, à fò) àwa jogún ìdẹ'ra


    Comentarios

    Envía preguntas, explicaciones y curiosidades sobre la letra

    0 / 500

    Forma parte  de esta comunidad 

    Haz preguntas sobre idiomas, interactúa con más fans de Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band y explora más allá de las letras.

    Conoce a Letras Academy

    ¿Enviar a la central de preguntas?

    Tus preguntas podrán ser contestadas por profesores y alumnos de la plataforma.

    Comprende mejor con esta clase:

    0 / 500

    Opciones de selección